Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ C

Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ C
Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ CElectron micrograph of hepatitis C virus purified from cell culture (scale = 50 nanometers)
Electron micrograph of hepatitis C virus purified from cell culture (scale = 50 nanometers)
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-1017.1, 18.2 17.1, 18.2
ICD/CIM-9070.70,070.4, 070.5 070.70,070.4, 070.5
OMIM609532
DiseasesDB5783
MedlinePlus000284

Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ C jẹ́ àrùn tí ó jẹ́ pé ẹ̀dọ̀ ni ó kọ́kọ́ máa n ṣe àkóbá fún. Kòkòrò-àrùn Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ C ni ó máa n fa àrùn náà.[1] Hepatitis C kì í sáábà ní ìmọ̀lára-àìlera, sùgbọ́n èyí tí ó bá ti wọ ara gan an lè dá ọgbẹ́ sí ara ẹ̀dọ̀, tí ó sì lè yí sí àìsàn ẹ̀dọ̀ míràn tí a mọ̀ sí cirrhosis lẹ́yìn ọdún díẹ̀. Ní àwọn ìgbà míràn, àwọn ènìyàn tí ó bá ní àìsàn ẹ̀dọ̀ tí n jẹ́ cirrhosis àìlera ẹ̀dọ̀ parí-iṣẹ́, jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀, tàbí kí ó mú kí gògò-ń-gò àti ikùn wú bọ-bọ-ọ-bọ, èyí tí ó sì le yọrí sí sìsun ẹ̀jẹ̀ tí ó mú ikú lọ́wọ́.[1]

Ọ̀nà àkọ́kọ́ tí àwọn ènìyàn ti máa n ṣe àgbákò àrùn hepatitis C jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀-kan-ẹjẹ̀ ní ìgbà tí ènìyàn bá n gba ìtọ́jú fífa òògùn sínú isan ara, àwọn ohun èlò iṣẹ́ ìlera tí a kò bọ̀ lórí iná kí a tó lò wọn, àti nípa gbígba ẹ̀jẹ̀ sí ara. Ó tó miliọnu 130–170 káàkiri àgbáye tí wọn ní àrùn hepatitis C. Àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìwádìí lóri kòkòrò-àrùn HVC ni ààrin ọdún 1970, tí wọn sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọdún 1989 pé àrùn tí n jẹ́ bẹ́ẹ̀ wà.[2] Kò tí ì hàn bóyá kòkòrò náà lè fa àìsàn si ara ẹranko.

Peginterferon àti ribavirin ni àwọn òògùn tí ó yẹ fún kòkòrò-àrùn HCV. Ìdá ààdọ́ta sí ọgọ́rin ninu ọgọ́rùn ún ènìyàn tí a fún ní òògù yìí ni wọn gba ìmúláradá. Àwọn tí wọn ní àìsàn ẹ̀dọ̀ cirrhosis tàbí jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀ lè nílò ìpààrọ̀ ẹ̀dọ̀, sùgbọ́n kòkòrò-àisàn yìí a tún lè jẹ jáde lẹyìn ìpààrọ̀ ẹ̀dọ̀ náà.[3] Kò sí abẹ́rẹ́-àjẹsára fún hepatitis C.

Àwọn àmì àti Ìmọ̀lára-àìsàn

Ìwọ̀nba ìdá mẹ́ẹ̀dógún ninu ọgọrun un àìsàn Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ C ni ó máa n mú ìmọ̀lára-àìsàn lọ́wọ́.[4] Àwọn ìmọ̀lára-àìsàn kì í sáàbà le ni ara, wọn kì í sì fi ojú hàn dáradára, lára wọn ni kí oúnjẹ má wù ènìyàn jẹ, kí ó máa rẹ̀ ènìyàn, kí èébì máa gbé ni, ìrora inu-ẹran ara tàbí ìrora oríkèé-ríkèé ara, kí ènìyàn máa rù.[5] Díẹ̀ péré lára àwọn àìsàn tí ó wọ aláìsàn náà lára ni ó máa n mú ibà-ọmọdé lọ́wọ́.[6] Àìsàn náà a máa lọ fúnrarẹ̀ ní ara ìdá mẹ́wàá sí àádọ́ta ninu ọgọ́rùn ún àwọn ènìyàn tí ó bá mú, tí ó sì máa n tètè kúrò lára àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ju àwọn yooku lọ.[6]

Àìsàn tí ó ti wọ ara gan an

Ìdá ọgọ́rin ninu ọgọ́rùn ún àwọn ènìyàn tí kòkòrò-àrùn yìí bá jà ní ó máa n wọ̀ lára gan an.[7] Ọ̀pọ̀ ni ó máa n ní ìmọ̀lára-àìsàn ní ìwọ̀nba, tàbí kí wọn má tilẹ̀ ní ìmọ̀lára yìí rárá ní ààrin ọdún mẹ́wàá àkọ́kọ́ tí wọn ti ní àìsàn nàá lára, [8] bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn hepatitis C máa n mú ara rírẹ̀ lọ́wọ́.[9] Hepatitis C ní okùnfà àkọ́kọ́ fún àìsàn-ẹdọ̀ cirrhosis àti jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀ láàrin àwọn tí àrùn yìí n bá já fún ọdún díẹ̀.[3] Láàrin ìdá mẹ́wàá sí ọgbọ̀n ninu ọgọrun un tí wọn ni àìsàn náà fún bí i ọgbọ̀n ọdún ni wọn ni àìsàn-ẹ̀dọ̀ cirrhosis.[3][5] Àìsàn-ẹ̀dọ̀ cirrhosis wọ́pọ̀ júlọ láàrin àwọn tí wọn ní àìsàn hepatitis B tàbí àìsàn-kò-gbóògùn HIV, àwọn ọ̀mùtípara, àti ni àárin áwọn ọkùnrin.[5] Àwọn tí wọn ní àìsàn-ẹ̀dọ̀ cirrhosis n bẹ ninu ewu nla pé wọn yóò ní jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀, èyí tí í ṣe ìdá kan sí mẹ́ta ninu ọgọ́rùn ún láàrin ọdún kan.[3][5] Fún àwọn ọ̀mùtípara, ewu àìsán náà tó ìlọ́po ọgọ́rùn ún lọ́dọ̀ wọn.[10] Hepatitis C ni ó máa n fa àísàn-ẹ̀dọ̀ cirrhosis tí ó tó ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ninu ọgọrùn ún àti àìsàn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀ tí ó tó ìdá márùndínlọ́gbọ̀n ninu ọgọrùn ún.[11]

Àísàn-ẹ̀dọ̀ cirrhosis tún lè yọrí sí ìfúnpá gíga ninu àwọn iṣan ara ti wọn so pọ̀mọ́ ẹ̀dọ̀, kí omi ara rọgún sínú ikùn, awọ-ara tí kò gbó tàbí ìsun ẹ̀jẹ̀, iṣan tí ó fẹ̀ sí i, pàápàá ninu ikùn àti ní gògò-n-gò, ibà-àyìnrín (kí awọ-ara pọ́n bí), àti àkóbá ọpọlọ.[12]

Àwọn àkóbà míràn yàtọ̀ fún ti ẹdọ̀

Àìsàn Hepatitis C tún jẹ́ ọ̀rẹ́ àìsàn àìsàn Sjögren's syndrome (irú àìlera kan tí n mú àgọ̀-ara dá àbò àìnídìí bo ararẹ̀), tí àwọn awo ẹ̀jẹ̀ kò tó bí ó ti yẹ, àìsàn awọ-ara, àìsàn ìtọ̀-súgà, àti àìsàn jẹjẹrẹ tí kì í ṣe Hodgkin.[13][14]

Other Languages
azərbaycanca: Hepatit C
تۆرکجه: هپاتیت سی
беларуская: Гепатыт C
беларуская (тарашкевіца)‎: Гепатыт С
български: Хепатит C
català: Hepatitis C
čeština: Hepatitida C
Deutsch: Hepatitis C
ދިވެހިބަސް: ހެޕަޓައިޓިސް ސީ
Ελληνικά: Ηπατίτιδα C
English: Hepatitis C
español: Hepatitis C
eesti: C-hepatiit
euskara: C hepatitis
فارسی: هپاتیت سی
français: Hépatite C
galego: Hepatite C
עברית: הפטיטיס C
hrvatski: Hepatitis C
magyar: Hepatitis C
Հայերեն: Հեպատիտ C
Bahasa Indonesia: Hepatitis C
italiano: Epatite C
日本語: C型肝炎
ქართული: C ჰეპატიტი
한국어: C형 간염
Кыргызча: Гепатит С
Latina: Hepatitis C
lietuvių: Hepatitas C
latviešu: C hepatīts
македонски: Хепатит Ц
монгол: Гепатит С
Bahasa Melayu: Hepatitis C
Nederlands: Hepatitis C
norsk nynorsk: Hepatitt C
português: Hepatite C
română: Hepatită C
русский: Гепатит C
srpskohrvatski / српскохрватски: Hepatitis C
Simple English: Hepatitis C
slovenčina: Hepatitída typu C
slovenščina: Hepatitis C
shqip: Hepatiti C
српски / srpski: Хепатитис Ц
svenska: Hepatit C
Kiswahili: Homanyongo C
тоҷикӣ: Ҳепатити Си
Tagalog: Hepataytis C
Türkçe: Hepatit C
українська: Гепатит C
Tiếng Việt: Viêm gan siêu vi C
中文: 丙型肝炎
粵語: 丙型肝炎