Egungun

EGUNGUN

egungun je okan pataki ninu awon Orisa akunlebo ni ile Yoruba. Egungun ni a tun mo si ara orun, awon Yoruba gbagbo pe nigba ti egun ba jade pe oku orun lo wa lati wa ba awon eyan re pejo, lati wa ba araye jiroro. Eegun je Orisa kan to ma n fi aso Bo gbogbo ara, aso yii si la mo si eku tabi agò. Nigbakugba ti egungun ba ma jade, oru ayajo ojo yii ma n je ojo ayeye nla, o ma je ojo idunu ati ojo irawo ebe si awon oku orun tori awon Yoruba gbogbo pe omo ina la n ran si ina leyi to tumo si pe oku la n ran so oku ti yio si le Jise ni kiakia. Awon Yoruba a ma fun egun lebu won a si ma tara rawo ebe si olorun fun ohun rere kan tabi omiran.Awon Awo tabi awon ti o ni igbagbo tabi ti won my egungun sise ni okunkundun ni awon ti a no si awon Oloje, awon won yii lo n Se ki Kari ni won so no pupo ni pa asiri eegun. Die lara awon oloye eegun ni:Alaagba Iyamoje Atokun egungun BojutoApenaIya agon abbl.O je okan pataki lara ewo oro; a ki I foko ko le nigbale, omiran tun ni pe eegun o gbodo te fuku agbado mole, atiwipe bi eegun ba n padan lowo ojo o gbodo ro ba.Atokunrin atobinrin lo n sawo egungun. Osan gangan si ni eegun ma n jade. Awon elegun won ma n padan lorisiirisii.

Egungun je Orisa kan ni ile Yoruba ti a n bo lati ri aanu, ojurere, omo, iyawo tabi ohun ti a ba fe gba. 


Orisiirisii ni eegun ti a ni won oruko won so yato lati adugbo kan si omiran. A ni awon eegun Alagbada; awon won Yi ni eegun to ma n yi aso. A ni eegun ti a mo si eegun Ajofoyinba;eegun yii lo ma n pesa, a ni eegun Alaago; awon eegun won yii je eegun oni faaji, ati awon eegun Miran to yato lati Ilu kan si omiran.

ITAN TO RO MO EGUNGUN

Onirunrun itan lo ro mo Iwasayi tabi ibere egungun sugbon eyi ti a o salaye ni Itan akoni ti a mo si Ogogo omo kulodo. 

Ogogo omo kulodo je akinkanju jagunjagun ni Ilu Oyo, no ojo kan iro kan Alaafin Oyo leti pe awon kan n kogun Bo lati wa ba Ilu Oyo, kin ni Alaafin gbo yii si ni o yara ke si Ogogo jagunjagun lati wa lo koju awon ota sebi koju ma ribi gbogbo ara bayi logun e. Nigba ti Ogogo omo kulodo doju ogun o ja ajasegun o Segun ota o reyin odi, bi o Se fe ma pada sile isele buruku kan se! Okan ninu awon ota won ni o moribo ninu iku ojona ti o si pawoda to tun Awo Se lo ba mu kini kan jade lati inu apo e loba fi meji kun ookan lo sa a bi oloogun ti n gbe sa a Lo ba fe fife to fe kini ohun konge ara ku lodo lo se, ni kulodo o ba le sokunrin mo, Ogogo wa so fun awon omo ogun e pe ko lo so fun won Nile pe ohun Ogogo omo kulodo ti bogun lo ati wi pe ohun a ma yoju si won lorekore. Leyin odun kan Ogogo ranse si awon ara oyo pe ohun n Bo ki won gbalugbajo, ki no mura ati gba alejo ohun, o si tun so fun omo e pe ki o ran aso wa fun ohun, eyi ti yio boju buse ti ko si ni fi ago ara kankan sile. Ojo ti Ogogo da ohun pe awon ara Ilu Oyo n reti alejo to n bo, awon kan tile n seye meji pe bawo ni ara orun sele waye, Ogogo o de titi o fi dojoro nigba ti oorun ti pari Ise oojo e. Nigba ti Ogogo wolu ko si eni to RI Oju tabi nnkankan lara e sugbon ohun re je tan Omole si iru eni ti n be ninu eku. Ogogo si n se bayi ni ododun.Eyi je okan lara ITAN to ro mo iwasaye egungun. Ko fe e si Ilu kan ni ile Yoruba ti ko ni egungun.

  • itokasi

Itokasi

Other Languages
Afrikaans: Been
Alemannisch: Knochen
አማርኛ: አጥንት
Ænglisc: Bān
العربية: عظم
ܐܪܡܝܐ: ܓܪܡܐ
অসমীয়া: হাড়
asturianu: Güesu
Aymar aru: Ch'aka
azərbaycanca: Sümük
Boarisch: Boana
беларуская: Косць
беларуская (тарашкевіца)‎: Косьць
български: Кост
বাংলা: হাড়
brezhoneg: Askorn
bosanski: Kost
català: Os
Mìng-dĕ̤ng-ngṳ̄: Gáuk-gáuk
کوردی: ئێسک
corsu: Ossu
čeština: Kost
Чӑвашла: Шăмă
Cymraeg: Asgwrn
Deutsch: Knochen
Zazaki: Este
Ελληνικά: Οστό
English: Bone
Esperanto: Osto
español: Hueso
eesti: Luu
euskara: Hezur
فارسی: استخوان
suomi: Luu
français: Os
Gaeilge: Cnámh
Gàidhlig: Cnàmh
galego: Óso
Avañe'ẽ: Kangue
Bahasa Hulontalo: Tulalo
客家語/Hak-kâ-ngî: Kut-kak
עברית: עצם
हिन्दी: अस्थि
hrvatski: Kost
Kreyòl ayisyen: Zo
magyar: Csont
հայերեն: Ոսկոր
interlingua: Osso
Bahasa Indonesia: Tulang
Ido: Osto
íslenska: Bein
italiano: Osso
日本語:
Basa Jawa: Balung
ქართული: ძვალი
Kabɩyɛ: Mɔɔyɛ
қазақша: Сүйек
ಕನ್ನಡ: ಮೂಳೆ
한국어:
kurdî: Hestî
лакку: ТтаркI
Lingua Franca Nova: Oso
Limburgs: Knaok
lumbaart: Òs
lingála: Mokúwa
lietuvių: Kaulas
latviešu: Kauls
Basa Banyumasan: Balung
олык марий: Лу
македонски: Коска
മലയാളം: അസ്ഥി
монгол: Яс
मराठी: अस्थि
Bahasa Melayu: Tulang
မြန်မာဘာသာ: အရိုး
مازِرونی: استکا
Nāhuatl: Omitl
नेपाल भाषा: क्वँय्
Nederlands: Bot (anatomie)
norsk nynorsk: Knokkel
occitan: Òs
ଓଡ଼ିଆ: ହାଡ଼
ਪੰਜਾਬੀ: ਹੱਡੀ
Pangasinan: Pokel
polski: Kość
پنجابی: ہڈی
português: Osso
Runa Simi: Tullu
română: Os (anatomie)
armãneashti: Osu
русский: Кость
संस्कृतम्: अस्थि
ᱥᱟᱱᱛᱟᱲᱤ: ᱡᱟᱝ
Scots: Bane
srpskohrvatski / српскохрватски: Kosti
Simple English: Bone
slovenčina: Kosť
slovenščina: Kost
Soomaaliga: Laf
српски / srpski: Кост
Basa Sunda: Tulang
svenska: Ben (skelett)
Kiswahili: Mfupa
தமிழ்: எலும்பு
తెలుగు: ఎముక
тоҷикӣ: Устухон
Setswana: Lerapo
Türkçe: Kemik doku
українська: Кістка
اردو: ہڈی
oʻzbekcha/ўзбекча: Suyak
Tiếng Việt: Xương
Volapük: Bom
walon: Oxhea
Winaray: Bukog
მარგალური: ყვილი
Vahcuengh: Ndok
中文: 骨骼
Bân-lâm-gú: Kut
粵語: